Tí àwọn Yorùbá bá pé ènìyàn kan ní “SOLIU ELÉNU GBÒÒRÒ” ájéwípé asòrò sobótọ̀ ni ẹni náà òrò èébú sì ni òpòlopò ènìyàn káà sí sùgbón njé èyin mọ̀ wípé ènìyàn nlá kán ni Soliu Elenu Gbòòrò yí?
Àwọn àgbà fi yé wa wípé nígbà ayé Aláàfin Adéyemí ìkínní ní Bàbá Soliu yìí gba orúko náà, kódà ọ̀rẹ́ tímótímó ni Soliu àti Ọba Adéyemí.
Olówó àti Olókìkí kan ní Soliu yìí, ìlú aawé ní ìpínlè Òyó ní ọkọ rè wá, orí ọkọ Soliu ijọ nàà ni Ilé ejò gíga tí ìlú Òyó (Oyo High Court) àti Technical College, Aawé dúró lẹ lórí báyìí.
Owó àti òkìkí tí Soliu ní yìí àti ìbáṣepọ̀ rè pèlú Ọba Adéyemí fún ní ìgboyà láti dásí òrò olórò yálà òrò lóko láyà tàbí òrò mòlébí soliu a máà ti ẹnu bo gbọgbọ rè. Ìdí nì yìí tí wón fi só ní SOLIU ELÉNU GBA-ÒRÒ.
Àkíyèsí pàtàkì: àkàwé lásán ní àwòrán yìí
Peoplesmind
Yorubablog