Ìtàn mi t’òní dá lórí ọkùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Adégbọrọ̀. Ọmọ bíbí ìlú Ìbàdàn ni Adégbọrọ̀ jẹ́. Ó tiraka ṣùgbọ́n kò r’ọ́wọ́ mú ní ìlú tí a bí si. Nítorí náà ó gba ara rẹ̀ ní ọ̀ràn, ó sì gba ọ̀nà ìlú Èkó lọ.
Nígbà tí Adégbọrọ̀ dé ìlú Èkó, ó k’ọrí sí ọjà Òyìngbò ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ní gb’àárù. Ni inú ọjà, Adégbọrọ̀ gbá’jú mọ́ iṣẹ́ rẹ̀, kò mu ìmukúmu, kò fa ìfàkúfà, bẹ́ẹ̀ kò tẹ̀lẹ́ obìrin kiri. Pàápàá jùlọ, Adégbọrọ̀ kò fi ọwọ́ mẹ́wẹ̀ẹ̀wá jẹun. Bí ó ti ń gba àárù, ló ń fi owó pamọ́, ó sì ń tele tọ́rọ́ kọ́bọ̀ tó ń pa lojoojumo. Lẹ́hìn ọdún mẹ́ta tí ó ti ń gba àárù nínú ọjà òyìngbò, ó ra omolanke kan, ó sì fi ń gb’àárù káàkiri ọjà Òyìngbò. Bí Adégbọrọ̀ ṣe kúrò l’áwùjọ àwọn tí ń fi orí ru ẹrù kiri ọjà Òyìngbò nù un o.
Lẹ́yìn ọdún mẹ́ta mìíràn, Adégbọrọ̀ ti tu owó jọ si, ó tún ra omolanke mẹ́ta mọ́ ẹyọ ọkàn tó wà nílẹ̀. Omolanke rẹ̀ wá di mẹ́rin. Adégbọrọ̀ wá di ẹni tí ń ya àwọn aláàárù ẹgbẹ́ rẹ̀ ni ọmọlanke. Wọ́n á gba ọmọlanke lọ́wọ́ rẹ̀ láàárọ̀, tó bá di lálẹ́ wọn á wá da padà, wọ́n á sì sanwó fún un.
Adégbọrọ̀ kò torí àjò gbàgbé ilé. A máa rántí ilé, a sì máa lọ sí ìlú Ìbàdàn lóòrè-kóòrè. Kódà ó ra ilẹ̀ sí ọjà ọba ní àdúgbò tí wọ́n bí i si ni ìlú Ìbàdàn, ó sì ń kọ́ ilé rẹ̀ díẹ̀díẹ̀. Nígbàkúgbà tí ó bá ti lọ sí Ìbàdàn, a máa ṣe fàájì pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ tí ó fi sílẹ̀ lọ ìlú Èkó. Ní ọjọ́ kan àwọn ọ̀rẹ́ Adégbọrọ̀ béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ wípé “ọ̀rẹ́ wa, ó mà ti ń ta bíọ́bíọ́… O ra ilẹ̀, ọ sì tún ń kọ́lé! Dákun wí fún wa, kíni àṣírí ọrọ̀ rẹ?” Adégbọrọ̀ sì dá wọn lóhùn wípé “Iṣẹ́ àṣekára ni o…iṣẹ́ aláàárù.” Àwọn ọ̀rẹ́ Adégbọrọ̀ yíjú sí ara wọn, wọ́n sì rẹ́rìn tàkìtì. Wọ́n f’èsì wípé. “Àárù kẹ̀? Ṣé iṣẹ́ nù un, àbí Ọlọ́run jẹ́ a gbádùn? Ọlọ́run má jẹ́ o! Àwa ò le gb’àárù láyé wa.” Wọ́n á tún máa fi Adégbọrọ̀ ṣe yẹ̀yẹ́, wọ́n á pè é ní Adégbọrọ̀ Aláàárù. Adégbọrọ̀ kò jẹ́ kí yẹ̀yẹ́ àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ dùn ún. Ó túbọ̀ tẹ’pá mọ́’ṣẹ́, ó sì ń re owó jọ síwájú sí.
Lẹ́yìn ọdún mẹ́ta míràn, owó tabua wá dé fún Adégbọrọ̀. Ó ra ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ kan. Kò pẹ́, kò jìnnà, ó tún ra ọkọ̀ mẹ́rin miran si, ó sì tún parí ilé tí ó ń kọ́ sí ìlú Ìbàdàn. Ilé náà yááyì púpọ̀, ẹ̀ẹ̀gàn ni hẹ̀ẹ̀!
Ọjọ́ tí Adégbọrọ̀ ṣe ayẹyẹ ìṣílé náà, ayé gbọ́, ọ̀run sì mọ̀. Ó kó àwọn ọrẹ rẹ dání láti ìlú Èkó láti wá bàa ṣe àjọyọ ìṣílé. Ìyàlẹ́nu ńlá ló sì jẹ́ fún gbogbo wọn láti rí ilé rẹpẹtẹ tí ọ̀rẹ́ wọn kọ́. Gbogbo ènìyàn ń kí Adégbọrọ̀ kú oriire, wọ́n sì ń bá a yọ̀.
Ǹjẹ́ ẹ rántí àwọn ọrẹ Adégbọrọ̀ ọjọ́sí? Tọ̀… wọn kò gb’àárù o, ṣùgbọ́n wọn kò sún kúrò lójú kan. Ojú kan náà tí wọ́n wà láti ọdún kẹsàn-án tí Adégbọrọ̀ ti fi wọ́n sílẹ̀ lọ Èkó ló tún padà wá bá wọn. Wọ́n wá ń wo Adégbọrọ̀ t’ìyanu-t’ìyanu. Wọ́n wípé “Ọ̀rẹ́ wa, ọlá rẹ ti bú rẹ́kẹrẹ̀kẹ wàyìí!” Adégbọrọ̀ sì fèsì pé “Hẹ̀ẹ̀… Ọlá Ọlọ́run ni o. Àmọ́ ṣá, ẹni ò lè ṣe aláàárù l’Óyìngbò, kò ní lè ṣe bíi Adégbọrọ̀ l’Ọ́jà ọba o”.
Ẹ̀yin ènìyàn mi, ilè Adégbọrọ̀ sì ńbẹ̀ níwájú ààfin Olúbàdàn títí di òní. Ìtàn ìgbésí Adégbọrọ̀ tàn káàkiri gbogbo ilẹ̀ Yorùbá títí tí ó fi di òwe. Ìdí rèé tí Yorùbá fi ń pa á l’ówe wípé “ẹni tí kò lè ṣe aláàárù l’Óyìngbò, kò ní lè ṣe bíi Adégbọrọ̀ l’Ọ́jà ọba”.
Source: iyaileookan