Olowo Adeoye Ajike Atanneye kejì ni Ologho kejìdínlọ́gbọ̀n ní ìlú Owo, ọdún méjì ní Ologho náà fí jọba kí ó tó wàjà nínú oṣù ògún (August) ní ọdún 1940.
Ọmọ bíbí Olowo Atanneye kínní (I) a sì bi ní ọdún 1889, ó sisé pẹ̀lú àwọn a gé gẹdù ní ìlú Benin síwájú kí ó tó darapọ̀ mọ́ àwọn British Cotton Growing Association ní ìlú Òṣogbo.
Bákannáà ni ó sisé gégé bí alábòjútó owó ìyẹn treasurer fún Owo Native Administration ipò yìí ni ó wà kí ó tó di Ologho ní ọdún 1938.
Peoplesmind
Source: yorubablog